Eko Akete Ile Ogbon
Eko Aromi sa legbe legbe
Eko aro sese maja
Eko akete ilu okun alagbalugbu omi,
Ta lo ni elomi l'eko? ebiwon pe talo ni abatabutu baba omikomi, talo laabata buutu baba odo kodo
Eko adele ti angere nsare ju eniyan elese meji lo
Eni to o ba lo si ilu eko tiko ba gbon, Koda, bo lo si ilu oyinbo ko legbon mo
Afefe toni pon wa ni bebe okun ti yin, faaji to ni pan wa ni bebe osa
Eko omo osha nio ose, mase kutere, osha n gbobi, kutere n gbori
Eyin lomo afinju woja marin gbendeke, obun woja n wapa sio sio
Eyo o Aye'le Eyo o, Eyo baba n teyin to n fi golu n sere, eyin oni sanwo onibode, odilee
Ti oju o ba ti ehin igbeti, oju o ni t'eko le
Ogbomoso omo ajilete nbi won gbe n jeka ki won oto muko yangan
ogbomoso afogbo ja bi esu odara. Ngba ogbomoso ba se o n ti o se tan
Bo logbon inu osebi ere ni omo ajileten ba olu ware se ni. Ogun o jaja ki o kogbomoso ri e de inu oko esinmin
Ogbomoso Ajilete si ogo re l'a fe korin, Iwo t'a te s'arin odan, Okan ninu ilu Akin
Ibaruba niwon eledin ese, omo ode bare eti oya
Oun ni baba to se gbogbo won le patapata porogodo
Kekere asa omo ajuuju bala
Agbalagba asa omo ajuuju bala
Kekere ladaba subu tawon ti n je laarin ota
Oloumi kekke lo ti n soko won nile
Kekere lo ti n soko won lóki
Kekere lojo ti n soko won lona iju
ORIKI TAPA
Ọmọ Olubisi
Ọmọ aláro tin jogun ẹsin
Ọsọ eyi yẹ Tápà abiru ti ẹmi
Ọmọ ajifowurọ dana kulikuli
Ẹsọ wẹrẹ ara Ilodo nle Olubisi
Àyè Tapa lo wun mi
Boba digba oku Tapa mi o ni si nle
Wọn ni ẹ wo'tutu owu
Wọn ni ẹ wa'fara oyin
Otutu owu sọpọ
Afara oyin sọwọn gogo
Ọmọ adada-ku-ada
Ọmọ Onilero ti f'ẹsẹ jo bi iji
Ọmọ elegun mọ na n mọ
Adẹẹgbẹẹ mo se'bo ti na mi lekan ni?
Ọmọ onigunu ari nawo
Ọmọ onigunu ariyọ sẹsẹ
Ọmọ onigun ti fi kulikuli sọdun
Ẹ wi fẹni ti o gbọ
Ẹ ro fẹni ti o mọ
Ẹ sọ fun wọn pe Tapa loni'gunu
Ọsẹ wẹwẹ ara Ilodo
Olubisi ọmọ alaro lo lẹsin.
ORIKI ILARO
Eji ogogo omo iku lodo toti deri'lewa
Omo adiye sun won sebi kuku loku, kiwon to lotatan adiye dide oyan fanda
Ilaro omo erin lonibu omo efon lo nona
Omo pakan lakan leyin jijo awo ni gbori ile omo ina tin jo geregere lori omi
Ilaro omo aran o sunwon e ko nigbale omo oku eko omo ijagudu akara
Ogogo omo e ba oro omo ina esan ogbo jinijinji ama jo’le gerege
Ogogo tin yini lokun lapa omo oku dudu ti koya kunran
Omo kulodo to tideri’lewa omo kinikan o joye lesa, tobawa joye lesa nko ilesanmi lasan loba yin muwon je.
Ogogo lomo agbele jebu, omo yiyo lanyo nile baba tobiyin lomo
Ilaro omo ku la ngberi omo kulodo ao ki wan kuloko tan won di apon
Otojo kotojo tomo kulodo nbo lati oko egan loba pade omi sonte, egbon mu aburo na mu gbogbo eni tomu sonte lomu rogbo dan
Ijebu omo alare, omo awujale, omo arojo joye, omo alagemo ogun woyowoyo, Omo aladiye ogogomoga, omo adiye balokun omilili, ara orokun, ara o radiye, omo ohun seni oyoyonyo, oyoyo mayomo ohun seni olepani, omo dudu ile komobe se njosi, pupa tomo be se okuku sinle, omo moreye mamaroko, morokotan eye matilo, omo moni isunle mamalobe, obe tin benile komoile baba tobiwan lomo,
Omo onigbo ma’de, omo onigbo mawo mawo, omo onigbo ajoji magbodowo, ajoji tobawo gboro yio di ebora ile baba tobi wan lomo. Ijebu omo ere niwa, omo olowo isembaye, towo kuji to dode, koto dowo eru, koto dowo omo. Orisa jendabi onile yi, niwan finpe igba ijebu owo, kelebe ijebu owo, ito ijebu owo, dudu ijebu owo, pupa ijebu owo, kekere ijebu owo, agba ijebu owo. Ijebu ode ijebu ni, ijebu igbo ijebu ni, ijebu isara ijebu ni, ayepe ijebu, ikorodu ijebu ijebu noni, Ijebu Omo Oni Ile nla, Ijebu Omo Alaso nla! Ajuwaase ooo"
Ibadan mesi Ogo, nile Oluyole. Ilu Ogunmola, olodogbo keri loju ogun. Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya. Ilu Ajayi, o gbori Efon se filafila. Ilu Latosa, Aare-ona kakanfo. Ibadan Omo ajoro sun. Omo a je Igbin yoo,fi ikarahun fo ri mu. Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni, eyi too ja aladuugbo gbogbo logun, Ibadan ki ba ni s’ore ai mu ni lo s’ogun. Ibadan Kure! Ibadan beere ki o too wo o, Ni bi Olè gbe n jare Olohun. B’Ibadan ti n gbonile bee lo n gba Ajoji. Eleyele lomi ti teru-tomo ‘Layipo n mu. Asejire lomi abumu-buwe nile Ibadan. A ki waye
ka maa larun kan lara, Ija igboro larun Ibadan.
Ife ooye lagbo
Omo olodo kan oteere
Omo olodo kan otaara
Odo to san wereke,to san wereke
To dehinkunle oshinle to dabata
To dehinkunle adelawe to dokun
Onikee ko gbodo bu mu
Ababaja won ko gbodo Buwe
Ogedegede onisoboro ni yio mu omi do naa gbe
Soboro mi wumi,eje ki ibi dandan maa ba alabe
Won kii duro ki wa nife ooni,won kii bere ki wa nife ooye
Ko ga,ko bere laa ki wa nife oodaye
Bi won ko si ki wa nife,won kii to abere
Oju bintin la fi n wo ni
Emi wa ki oba nife,mo lo akun
Oba nii lo sese efun
Adimula,won a ni apalado
Bante gbooro,ni mufe wumi
Segi owo ati tese,
Kafari apakan ka dapakan si
Yeepa orisa,aso funfun
Oun nii mu ile olufe wumi
Apadari eni,apalado eniyan
Ebo ojoojumo,nii mu ile won su nii lo
Awa lomo oni fitila rebete
Ina ko nii ku nibe tosan toru
Ibe ni baba wa gbe n ka owo eyo
Awa lomo onilu kan,ilu kan
Ti won n fawo ekun se
Aketepe eti erin ni won fi nse osan re
Onikeke ko gbodo jo
Ababaja ko gbodo yese
Kikida onisoboro ni yio jo ilu naa ya
Ogun ko see da gbe
Baba taani ko mo wipe irin ti po lagbede
Oun ti o ba mu alagbede,ko ni mu eni to n fin ina
Powered by Blogger.